Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 11:23-27 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ó ní, “Àwọn ọ̀tá wa lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde láti inú ìlú wọn láti bá wa jà ninu pápá, ṣugbọn a lé wọn pada títí dé ẹnubodè ìlú wọn.

24. Àwọn tafàtafà bẹ̀rẹ̀ sí ta ọfà sí wa láti orí ògiri wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn ọ̀gágun rẹ, wọ́n pa Uraya náà pẹlu.”

25. Dafidi rán oníṣẹ́ náà sí Joabu pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí da ọkàn rẹ rú níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ẹnikẹ́ni kò lè mọ ẹni tí ogun yóo pa. Tún ara mú gidigidi, kí o sì gba ìlú náà.”

26. Nígbà tí Batiṣeba gbọ́ pé wọ́n ti pa ọkọ òun, ó ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.

27. Nígbà tí àkókò ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Dafidi ní kí wọ́n mú un wá sí ààfin, Batiṣeba sì di aya rẹ̀. Ó bí ọmọkunrin kan fún un, ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí ohun tí Dafidi ṣe.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 11