Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 10:16-19 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Hadadeseri ọba, bá ranṣẹ sí àwọn ará Siria tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn odò Yufurate, wọ́n bá wá sí Helamu. Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ni aṣiwaju wọn.

17. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, ó la odò Jọdani kọjá lọ sí Helamu. Olukuluku àwọn ará Siria dúró ní ipò wọn, wọ́n dojú kọ Dafidi, wọ́n sì bá a jagun.

18. Àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ọmọ ogun Siria pada, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ pa ẹẹdẹgbẹrin (700) ninu àwọn tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ogun Siria, ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ninu àwọn ẹlẹ́ṣin wọn. Wọ́n ṣá Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun wọn lọ́gbẹ́, ó sì kú sójú ogun.

19. Nígbà tí àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn Hadadeseri rí i pé, àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Láti ìgbà náà ni ẹ̀rù sì ti ń ba àwọn ará Siria láti ran àwọn ará Amoni lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 10