Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 1:3-16 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Láti inú àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli ni mo ti sá àsálà.”

4. Dafidi wí fún un pé, “Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún mi.”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Sísá ni àwọn ọmọ ogun Israẹli sá kúrò lójú ogun, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọ́n sì ti pa; wọ́n ti pa Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ pẹlu.”

5. Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ ti kú?”

6. Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Orí òkè Giliboa ni mo wà, ni mo déédé rí Saulu tí ó fara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀. Mo sì rí i tí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ọ̀tá ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ń lépa rẹ̀.

7. Bí ó ti bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí. Mo sì dá a lóhùn pé, ‘Èmi nìyí.’

8. Ó bi mí pé, ta ni mí; mo dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀kan ninu àwọn ará Amaleki ni mí.’

9. Saulu bá wí fún mi pé, ‘Sún mọ́ mi níhìn-ín, kí o pa mí, nítorí pé mo ti fara gbọgbẹ́, mò ń jẹ̀rora gidigidi, ṣugbọn ẹ̀mí mi ṣì wà sibẹ.’

10. Mo bá súnmọ́ Saulu, mo sì pa á. Nítorí mo mọ̀ pé, tí ó bá kúkú ṣubú lulẹ̀, yóo kú náà ni. Mo bá ṣí adé orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ni mo kó wá fún ọ yìí, Dafidi, oluwa mi.”

11. Ni Dafidi ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn.

12. Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun.

13. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ ọdọmọkunrin tí ó wá ròyìn fún un pé, “Níbo ni o ti wá?”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ará Amaleki kan, tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli ni mí.”

14. Dafidi tún bi í pé, “Báwo ni ẹ̀rù kò ṣe bà ọ́ láti pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn?”

15. Ni Dafidi bá pàṣẹ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, lọ pa ọdọmọkunrin ará Amaleki náà. Ọkunrin náà bá pa á.

16. Dafidi wí fún ọdọmọkunrin ará Amaleki náà pé, “Ìwọ ni o fa èyí sí orí ara rẹ. Ìwọ ni o dá ara rẹ lẹ́bi, nípa jíjẹ́wọ́ pé, ìwọ ni o pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 1