Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 1:19-27 BIBELI MIMỌ (BM)

19. “A! Israẹli, wọ́n ti pa àwọn tí o fi ń ṣògo lórí àwọn òkè rẹ!Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú!

20. Ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀ ní Gati,ẹ má ṣe ròyìn rẹ̀ ní ìgboro Aṣikeloni;kí inú àwọn obinrin Filistini má baà dùn,kí àwọn ọmọbinrin àwọn aláìkọlà má baà máa yọ̀.

21. “Ẹ̀yin òkè Giliboa,kí òjò má ṣe rọ̀ le yín lórí,bẹ́ẹ̀ ni kí ìrì má ṣe sẹ̀ sórí yín,kí èso kan má so mọ́ ní gbogbo orí òkè Giliboa,nítorí pé, ibẹ̀ ni apata àwọn akikanju ti dípẹtà;a kò sì fi òróró kun apata Saulu mọ́.

22. Ọrun Jonatani kì í pada lásán,bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í pada,láì fi ẹnu kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa,ati ọ̀rá àwọn akikanju.

23. “Saulu ati Jonatani,àyànfẹ́ ati eniyan rere,wọn kì í ya ara wọn nígbà ayé wọn,nígbà tí ikú sì dé,wọn kò ya ara wọn.Wọ́n yára ju àṣá lọ,wọ́n sì lágbára ju kinniun lọ.

24. “Ẹ̀yin obinrin Israẹli,ẹ sọkún nítorí Saulu,ẹni tí ó ro yín ní aṣọ elése àlùkò,tí ó sì fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́.

25. “Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú lójú ogun!Jonatani ti ṣubú lulẹ̀,wọ́n ti pa á lórí òkè.

26. “Mò ń ṣe ìdárò rẹ,Jonatani arakunrin mi;o ṣọ̀wọ́n fún mi lọpọlọpọ.Ìfẹ́ tí o ní sí mi, kò ṣe é fi ẹnu sọ,ó ju ìfẹ́ obinrin lọ.

27. “Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú,tí àwọn ohun ìjà ogun sì ń ṣègbé!”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 1