Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 9:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní ilẹ̀ Hadiraki yóo jìyà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlú Damasku. Nítorí pé OLUWA ló ni àwọn ìlú Aramu, bí ó ti ni àwọn ẹ̀yà Israẹli.

2. Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

3. Ìlú Tire ti mọ odi ààbò yí ara rẹ̀ ká, ó ti kó fadaka jọ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ó sì rọ́ wúrà jọ bíi pàǹtí láàrin ìta gbangba.

4. Ṣugbọn OLUWA yóo gba gbogbo ohun ìní Tire, yóo kó gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ dà sinu òkun, iná yóo sì jó o ní àjórun.

5. Ìlú Aṣikeloni yóo rí i, ẹ̀rù yóo sì bà á, ìlú Gasa yóo rí i, yóo sì máa joró nítorí ìrora. Bákan náà ni yóo rí fún ìlú Ekironi, nítorí ìrètí rẹ̀ yóo di òfo. Ọba ìlú Gasa yóo ṣègbé, ìlú Aṣikeloni yóo sì di ahoro.

6. Oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ni yóo máa gbé Aṣidodu; ìgbéraga Filistia yóo sì dópin.

7. N óo gba ẹ̀jẹ̀ ati ohun ìríra kúrò ní ẹnu rẹ̀, àwọn tí yóo kù ninu wọn yóo di ti Ọlọrun wa; wọn yóo dàbí ìdílé kan ninu ẹ̀yà Juda, ìlú Ekironi yóo sì dàbí ìlú Jebusi.

8. Ṣugbọn n óo dáàbò bo ilé mi, kí ogun ọ̀tá má baà kọjá níbẹ̀; aninilára kò ní mú wọn sìn mọ́, nítorí nisinsinyii, èmi fúnra mi ti fi ojú rí ìyà tí àwọn eniyan mi ti jẹ.

9. Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni!Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín;ajagun-ṣẹ́gun ni,sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn.

10. OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu,òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu,a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun.Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia,ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkunati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé.

11. Ìwọ ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí mo fi bá ọ dá majẹmu,n óo dá àwọn eniyan rẹ tí a kó lẹ́rú sílẹ̀ láti inú kànga tí kò lómi.

12. Ẹ pada sí ibi ààbò yín,ẹ̀yin tí a kó lẹ́rú lọ tí ẹ sì ní ìrètí;mo ṣèlérí lónìí pé,n óo dá ibukun yín pada ní ìlọ́po meji.

13. Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi,mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀.Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà,láti pa àwọn ará Giriki run,n óo sì fi tagbára tagbára lò yínbí idà àwọn jagunjagun.

14. OLUWA yóo fara han àwọn eniyan rẹ̀,yóo ta ọfà rẹ̀ bíi mànàmáná.OLUWA Ọlọrun yóo fọn fèrè ogunyóo sì rìn ninu ìjì líle ti ìhà gúsù.

Ka pipe ipin Sakaraya 9