Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 8:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. bẹ́ẹ̀ ni mo tún pinnu nisinsinyii láti ṣe ẹ̀yin ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda ní rere. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù.

16. Àwọn nǹkan tí ó yẹ kí ẹ máa ṣe nìyí: ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ nílé ẹjọ́; èyí ni yóo máa mú alaafia wá.

17. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ara yín, ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké, nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni mo kórìíra.”

18. OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá Sakaraya sọ̀rọ̀, ó ní,

19. “Ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà ní oṣù kẹrin, oṣù karun-un, oṣù keje, ati oṣù kẹwaa yóo di àkókò ayọ̀ ati inú dídùn ati àkókò àríyá fun yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ ati alaafia.

20. “Ọ̀pọ̀ eniyan yóo ti oríṣìíríṣìí ìlú wá sí Jerusalẹmu,

21. àwọn ará ìlú kan yóo máa rọ àwọn ará ìlú mìíràn pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ kíákíá láti wá ojurere OLUWA, ati láti sin OLUWA àwọn ọmọ ogun; ibẹ̀ ni mò ń lọ báyìí.’

22. Ọpọlọpọ eniyan ati àwọn orílẹ̀-èdè ńlá yóo wá sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, wọn óo sì wá wá ojurere rẹ̀ ní Jerusalẹmu.

23. Nígbà tó bá yá, eniyan mẹ́wàá láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè yóo rọ̀ mọ́ aṣọ Juu kanṣoṣo, wọn yóo sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí á máa bá ọ lọ, nítorí a gbọ́ pé Ọlọrun wà pẹlu yín.’ ”

Ka pipe ipin Sakaraya 8