Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 7:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Tabi nígbà tí ẹ̀ ń jẹ tí ẹ sì ń mu, kì í ṣe ara yín ni ẹ̀ ń jẹ tí ẹ̀ ń mu fún?”

7. Nígbà tí nǹkan fi ń dára fún Jerusalẹmu, tí eniyan sì pọ̀ níbẹ̀, ati àwọn ìlú agbègbè tí ó yí i ká, ati àwọn ìlú ìhà gúsù ati ti ẹsẹ̀ òkè ní ìwọ̀ oòrùn; ṣebí àwọn wolii OLUWA ti sọ nǹkan wọnyi tẹ́lẹ̀?

8. OLUWA tún rán Sakaraya kí ó sọ fún wọn pé,

9. “Ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì fi àánú ati ìyọ́nú hàn sí ara yín.

10. Ẹ má máa fi ìyà jẹ àwọn opó, tabi àwọn aláìníbaba, tabi àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tabi àwọn aláìní. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ẹnikẹ́ni.”

11. Ṣugbọn àwọn eniyan kò gbọ́, wọ́n ṣe oríkunkun, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ tèmi.

12. Wọ́n ṣe agídí, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ òfin ati ọ̀rọ̀ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ rán sí wọn, láti ẹnu àwọn wolii. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun bínú sí wọn gidigidi.

13. “Nígbà tí mo pè wọ́n, wọn kò gbọ́, nítorí náà ni n kò fi ní fetí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí.

Ka pipe ipin Sakaraya 7