Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 6:10-15 BIBELI MIMỌ (BM)

10. “Lára àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ti oko ẹrú Babiloni dé, mú Helidai, Tobija ati Jedaaya lẹsẹkẹsẹ, kí o lọ sí ilé Josaya ọmọ Sefanaya.

11. Gba fadaka ati wúrà lọ́wọ́ wọn, kí o fi ṣe adé, kí o sì fi adé náà dé Joṣua olórí alufaa, ọmọ Jehosadaki lórí.

12. Kí o sì sọ ohun tí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí fún un, pé, ‘Wò ó! Ọkunrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka ni yóo gba ipò rẹ̀, òun ni yóo sì kọ́ ilé OLUWA.

13. Òun gan-an ni yóo kọ́ ọ, tí yóo sì gba ògo ati ẹ̀yẹ tí ó yẹ fún ọba, yóo sì jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀. Yóo ní alufaa gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn, wọn yóo sì máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní alaafia.’

14. Adé náà yóo wà ní ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí fún Helidai ati Tobija ati Jedaaya ati Josaya, ọmọ Sefanaya.

15. “Àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn réré yóo wá láti ba yín kọ́ ilé OLUWA. Ẹ óo wá mọ̀ dájú pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán mi si yín. Gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ patapata bí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́.”

Ka pipe ipin Sakaraya 6