Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 5:7-11 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nígbà tí wọ́n ṣí ìdérí òjé tí wọ́n fi bo agbọ̀n náà kúrò lórí rẹ̀, mo rí obinrin kan tí ó jókòó sinu eefa náà.

8. Angẹli náà sọ pé “Ìwà ìkà ni obinrin yìí dúró fún.” Ó ti obinrin náà pada sinu agbọ̀n eefa náà, ó sì fi ìdérí òjé náà dé e mọ́ ibẹ̀ pada.

9. Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ.

10. Mo bi angẹli náà pé, “Níbo ni wọ́n ń gbé e lọ?”

11. Ó dáhùn pé, “Ilẹ̀ Ṣinari ni wọ́n ń gbé e lọ, láti lọ kọ́lé fún un níbẹ̀. Tí wọ́n bá parí ilé náà, wọn yóo gbé e kalẹ̀ sibẹ.”

Ka pipe ipin Sakaraya 5