Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 2:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán ni sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ko yín lẹ́rú, nítorí ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín, fọwọ́ kan ẹyinjú èmi OLUWA.”

9. N óo bá àwọn ọ̀tá yín jà; wọn yóo sì di ẹrú àwọn tí ń sìn wọ́n.Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA àwọn ọmọ ogun.

10. OLUWA ní, “Ẹ kọrin ayọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín máa dùn, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, nítorí pé mò ń bọ̀ wá máa ba yín gbé.

11. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo parapọ̀ láti di eniyan mi nígbà náà. N óo máa gbé ààrin yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ranṣẹ si yín.

12. N óo jogún Juda bí ohun ìní mi ninu ilẹ̀ mímọ́, n óo sì yan Jerusalẹmu.”

13. Ẹ̀yin eniyan, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA, nítorí ó ń jáde bọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Sakaraya 2