Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 14:14-21 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Àwọn ará Juda pàápàá yóo máa bá àwọn ará Jerusalẹmu jà. A óo kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká jọ: ati fadaka, ati wúrà, ati ọpọlọpọ aṣọ.

15. Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú náà yóo kọlu àwọn ẹṣin, ìbakasíẹ, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá wà ní ibùdó ogun wọn.

16. Àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù láti àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu yóo máa wá lọdọọdun láti sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Jerusalẹmu ati láti ṣe Àjọ̀dún Àgọ́.

17. Bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò lọ sí ìlú Jerusalẹmu lọ sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, òjò kò ní rọ̀ sí ilẹ̀ rẹ̀.

18. Bí ó bá ṣe pé àwọn ará Ijipti ni wọ́n kọ̀ tí wọn kò wá síbi Àjọ̀dún Àgọ́ náà, irú àrùn tí OLUWA fi bá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò wá sí ibi Àjọ Àgọ́ jà, ni yóo dà lé wọn lórí.

19. Èyí ni ìyà tí yóo jẹ ilẹ̀ Ijipti ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò bá wá síbi Àjọ Àgọ́.

20. Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ.

21. Gbogbo ìkòkò tí ó wà ní Jerusalẹmu ati ní Juda yóo di mímọ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àwọn tí wọ́n wá ṣe ìrúbọ yóo máa se ẹran ẹbọ wọn ninu ìkòkò wọnyi. Kò ní sí oníṣòwò ní ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ tó bá di ìgbà náà.

Ka pipe ipin Sakaraya 14