Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 10:9-12 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn kásí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,sibẹsibẹ, wọn yóo ranti mi lọ́nà jíjìn tí wọ́n wà.Àwọn ati àwọn ọmọ wọn yóo wà láàyè,wọn yóo sì pada wá sí ilẹ̀ wọn.

10. N óo kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn láti ilẹ̀ Ijipti wá,n óo kó wọn jọ láti ilẹ̀ Asiria;n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Lẹbanoni,wọn óo kún ilẹ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ààyè mọ́.

11. Wọn óo la òkun Ijipti kọjá,ìgbì rẹ̀ yóo sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.Odò Naili yóo gbẹ kanlẹ̀,a óo rẹ ìgbéraga ilẹ̀ Asiria sílẹ̀,agbára óo sì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti.

12. N óo sọ wọ́n di alágbára ninu èmi OLUWA,wọn yóo sì máa ṣògo ninu orúkọ mi.”

Ka pipe ipin Sakaraya 10