Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 10:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ bèèrè òjò lọ́wọ́ OLUWA ní àkókò rẹ̀, àní lọ́wọ́ OLUWA tí ó dá ìṣúdẹ̀dẹ̀ òjò; Òun ló ń fún eniyan ní ọ̀wààrà òjò, tí àwọn ohun ọ̀gbìn fi ń tutù yọ̀yọ̀.

2. Ìsọkúsọ ni àwọn ère ń sọ, àwọn aríran ń ríran èké; àwọn tí ń lá àlá ń rọ́ àlá irọ́, wọ́n sì ń tu àwọn eniyan ninu lórí òfo. Nítorí náà ni àwọn eniyan fi ń rìn káàkiri bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.

3. OLUWA ní, “Inú mi ru sí àwọn olùṣọ́-aguntan, n óo sì fìyà jẹ àwọn alákòóso. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń tọ́jú agbo mi, àní àwọn eniyan Juda, wọn yóo sì dàbí ẹṣin alágbára lójú ogun.

4. Ninu wọn ni a óo ti rí òkúta igun ilé, tí a lè pè ní olórí, aṣaaju, ati aláṣẹ, láti ṣe àkóso àwọn eniyan mi.

5. Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin.

6. “N óo sọ ilé Juda di alágbára,n óo sì gba ilé Josẹfu là.N óo mú wọn pada,nítorí àánú wọn ń ṣe mí,wọn yóo dàbí ẹni pé n kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ rí;nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn,n óo sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ wọn.

7. Nígbà tó bá yá, ilé Efuraimu yóo dàbí jagunjagun alágbára,inú wọn yóo sì dùnbí inú ẹni tí ó mu ọtí waini.Nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá rí i,inú wọn yóo dùn,ọkàn wọn yóo sì yin OLUWA.

8. “N óo ṣẹ́wọ́ sí wọn,n óo sì kó wọn jọ sinu ilé.Mo ti rà wọ́n pada,nítorí náà wọn yóo tún pọ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

Ka pipe ipin Sakaraya 10