Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin.