Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 1:9-18 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Mo bá bèèrè pé, “OLUWA mi, kí ni ìtumọ̀ kinní wọnyi?”Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì dáhùn pé, “N óo sọ ìtumọ̀ wọn fún ọ.”

10. Ọkunrin tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni àwọn tí OLUWA rán láti máa rin ilẹ̀ ayé wò.”

11. Wọ́n sì jíṣẹ́ fún angẹli OLUWA, tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà pé, “A ti lọ rin ilẹ̀ ayé wò jákèjádò, a sì rí i pé wọ́n wà ní alaafia ati ìdákẹ́rọ́rọ́.”

12. Angẹli OLUWA bá dáhùn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó kí o tó yọ́nú sí Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, tí o tí ń bínú sí láti aadọrin ọdún sẹ́yìn?”

13. OLUWA sì dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn pẹlu ọ̀rọ̀ ìtùnú.

14. Angẹli náà bá sọ fún mi pé kí n lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Mo ní ìfẹ́ ati ìtara tí ó jinlẹ̀ pupọ fún Jerusalẹmu ati Sioni.

15. Inú sì ń bí mi gidigidi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà ní alaafia; nítorí pé, nígbà tí mo bínú díẹ̀ sí àwọn eniyan mi, wọ́n tún dá kún ìṣòro wọn ni.

16. Nítorí náà, mo ti pada sí Jerusalẹmu láti ṣàánú fún un: a óo tún ilé mi kọ́ sibẹ, a óo sì tún ìlú Jerusalẹmu kọ́.”

17. Angẹli náà tún sọ fún mi pé, “Lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, àwọn ìlú òun yóo tún kún fún ọrọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, òun OLUWA yóo tu Sioni ninu, òun óo sì tún yan Jerusalẹmu ní àyànfẹ́ òun.”

18. Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí ìwo mààlúù mẹrin,

Ka pipe ipin Sakaraya 1