Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 1:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí ìwo mààlúù mẹrin,

19. mo sì bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀.Ó bá dá mi lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn alágbára ayé tí wọ́n fọ́n Juda, Israẹli, ati Jerusalẹmu ká.”

20. Lẹ́yìn náà, OLUWA fi àwọn alágbẹ̀dẹ mẹrin kan hàn mí.

21. Mo bèèrè pé, “Kí ni àwọn wọnyi ń bọ̀ wá ṣe?”Ó bá dáhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn tí wọ́n fọ́n Juda ká patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ku ẹnìkan mọ́. Ṣugbọn àwọn alágbẹ̀dẹ wọnyi wá láti dẹ́rùba àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọ́n Juda ká, ati láti fọ́n àwọn náà ká.”

Ka pipe ipin Sakaraya 1