Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rutu 4:10-22 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ati pé, mo ṣú Rutu, ará Moabu, opó Maloni lópó, ó sì di aya mi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ohun ìní rẹ̀, ati pé kí á má baà mú orúkọ rẹ̀ kúrò láàrin àwọn arakunrin rẹ̀ ati ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ìlú baba rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.”

11. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ẹnu ọ̀nà ibodè ati àwọn àgbààgbà náà dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLUWA kí ó ṣe obinrin tí ń bọ̀ wá di aya rẹ bíi Rakẹli ati Lea, tí wọ́n bí ọpọlọpọ ọmọ fún Jakọbu. Yóo dára fún ọ ní Efurata, o óo sì di olókìkí ní Bẹtilẹhẹmu.

12. Àwọn ọmọ tí OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí fún ọ yóo kún ilé rẹ fọ́fọ́, bí ọmọ ti kún ilé Peresi, tí Tamari bí fún Juda.”

13. Boasi bá ṣú Rutu lópó, Rutu sì di aya rẹ̀. Nígbà tí Boasi bá a lòpọ̀, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan.

14. Àwọn obinrin bá sọ fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, tí kò ṣe ọ́ ní aláìní ìbátan, kí OLUWA ṣe ọmọ náà ní olókìkí ní Israẹli.

15. Ọmọ yìí yóo mú kí adùn ayé rẹ sọjí, yóo sì jẹ́ olùtọ́jú fún ọ ní ọjọ́ ogbó rẹ, nítorí iyawo ọmọ rẹ tí ó fẹ́ràn rẹ, tí ó sì ju ọmọkunrin meje lọ ni ó bímọ fún ọ.”

16. Naomi bá gba ọmọ náà, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì di olùtọ́jú rẹ̀.

17. Àwọn obinrin àdúgbò bá sọ ọmọ náà ní Obedi, wọ́n ń sọ káàkiri pé, “A bí ọmọkunrin kan fún Naomi.” Obedi yìí ni baba Jese tíí ṣe baba Dafidi.

18. Àwọn atọmọdọmọ Peresi nìwọ̀nyí: Peresi ni baba Hesironi;

19. Hesironi bí Ramu, Ramu bí Aminadabu;

20. Aminadabu bí Naṣoni; Naṣoni bí Salimoni;

21. Salimoni bí Boasi, Boasi bí Obedi;

22. Obedi bí Jese, Jese sì bí Dafidi.

Ka pipe ipin Rutu 4