Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Solomoni 1:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu,nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ.

3. Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn,orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde;nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ.

4. Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá,ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀.Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹa óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ;abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!

5. Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà,mo dàbí àgọ́ Kedari,mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni.

6. Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú,oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀.Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi,wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà,ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára.

7. Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́:níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko?Níbo ni wọ́n ti ń sinmi,nígbà tí oòrùn bá mú?Kí n má baà máa wá ọ kiri,láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ?

8. Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin,bí o kò bá mọ ibẹ̀,ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran.Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹkolẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan.

9. Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao.

Ka pipe ipin Orin Solomoni 1