Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 84:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,

2. ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí,àárò rẹ̀ ń sọ mí;tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀sí Ọlọrun alààyè.

3. Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé,àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ,àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,ọba mi, ati Ọlọrun mi.

4. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ,wọn óo máa kọ orin ìyìn sí ọ títí lae!

5. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn,tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún.

6. Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ,wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi;àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀.

7. Wọn ó máa ní agbára kún agbára,títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni.

8. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi;tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu!

9. Bojú wo àpáta wa, Ọlọrun,fi ojú àánú wo ẹni àmì òróró rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 84