Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 75:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́.À ń kéde orúkọ rẹ,a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

2. OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó,n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú.

3. Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún,ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú.

4. Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’;èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’

5. Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,ẹ má sì gbéraga.”

6. Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn,tabi láti ìwọ̀ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá.

7. Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú:á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga.

8. Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA,Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀,ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú,yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀;gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún,wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.

9. Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae,n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 75