Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 57:2-7 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi.

3. Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là,yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi.Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ati òtítọ́ rẹ̀ hàn!

4. Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí,àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra;eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà,ahọ́n wọn sì dàbí idà.

5. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.

6. Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi;ìpọ́njú dorí mi kodò.Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i.

7. Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun,ọkàn mi dúró ṣinṣin!N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 57