Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 57:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ṣàánú mi, Ọlọrun, ṣàánú mi,nítorí ìwọ ni ààbò mi;abẹ́ òjìji apá rẹ ni n óo fi ṣe ààbò mi,títí gbogbo àjálù wọnyi yóo fi kọjá.

2. Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi.

3. Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là,yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi.Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ati òtítọ́ rẹ̀ hàn!

4. Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí,àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra;eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà,ahọ́n wọn sì dàbí idà.

5. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.

6. Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi;ìpọ́njú dorí mi kodò.Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i.

7. Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun,ọkàn mi dúró ṣinṣin!N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.

8. Jí, ìwọ ọkàn mi!Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu,èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu.

9. OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan;n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

10. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.

11. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 57