Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 53:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé,“Kò sí Ọlọrun.”Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe,kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere.

2. Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá,ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé,àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun.

3. Gbogbo wọn ni ó ti yapa;tí wọn sì ti bàjẹ́,kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo.

4. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,àní àwọn tí kì í ké pe Ọlọrun.

5. Ẹ wò wọ́n, bí wọ́n ṣe wà ninu ẹ̀rù ńlá,ẹ̀rù tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí!Nítorí Ọlọrun yóo fọ́n egungun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká;ojú óo tì wọ́n, nítorí Ọlọrun ti kọ̀ wọ́n.

6. Ìbá ti dára tó, kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!Nígbà tí Ọlọrun bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 53