Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 5:4-12 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú;àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé.

5. Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ;o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi.

6. O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run;OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn.

7. Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,èmi óo wọ inú ilé rẹ;n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ.

8. OLUWA, tọ́ mi sọ́nà òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi;jẹ́ kí ọ̀nà rẹ hàn kedere níwájú mi.

9. Nítorí kò sí òtítọ́ kan lẹ́nu wọn;ìparun ni ó wà ninu ọkàn wọn.Isà òkú tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;ẹnu wọn kún fún ìpọ́nni ẹ̀tàn.

10. Dá wọn lẹ́bi, Ọlọrun, kí o sì fìyà jẹ wọ́n;jẹ́ kí ìgbìmọ̀pọ̀ wọn ó gbé wọn ṣubú.Ta wọ́n nù nítorí ọ̀pọ̀ ìrékọjá wọn,nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

11. Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn,kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae.Dáàbò bò wọ́n,kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ.

12. Nítorí ìwọ OLUWA a máa bukun àwọn olódodo;ò sì máa fi ojurere rẹ tí ó dàbí apata dáàbò bò wọ́n.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 5