Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 45:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èrò rere kan ń gbé mi lọ́kàn,mò ń kọ orin mi fún ọbaahọ́n mi dàbí gègé akọ̀wé tó mọṣẹ́.

2. Ìwọ ni o dára jùlọ láàrin àwọn ọkunrin;ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ,nítorí náà Ọlọrun ti bukun ọ títí ayé.

3. Sán idà rẹ mọ́ ìdí, ìwọ alágbára,ninu ògo ati ọlá ńlá rẹ.

4. Máa gun ẹṣin ìṣẹ́gun lọ ninu ọlá ńlá rẹ,máa jà fún òtítọ́ ati ẹ̀tọ́,kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ fún ọ ní ìṣẹ́gun ńlá.

5. Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n gún àwọn ọ̀tá ọba lọ́kàn,àwọn eniyan ń wó lulẹ̀ níwájú rẹ.

6. Ìjọba tí Ọlọrun fún ọ wà lae ati laelae.Ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ ẹ̀tọ́ ni.

7. O fẹ́ràn òdodo, o sì kórìíra ìwà ìkànítorí náà ni Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmì òróró yàn ọ́.Àmì òróró ayọ̀ ni ó fi gbé ọ gaju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ lọ.

8. Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari,láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 45