Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 40:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ,ṣugbọn o là mí ní etí;o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

7. Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé;a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé:

8. mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi;mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”

9. Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá.Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́,gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀.

10. Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́.Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ;n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu àwùjọ ńlá.

11. Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA,sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́.

12. Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká,ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí,tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran.Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,ọkàn mi ti dàrú.

13. OLUWA, dákun gbà mi;yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

14. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́gba ẹ̀mí mi,kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata,jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,kí wọ́n sì tẹ́.

15. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n,kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú,àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi.

16. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀,kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ;kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹmáa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!”

17. Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí;ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi.Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi,má pẹ́, Ọlọrun mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 40