Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 18:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi.

2. OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi;Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà.Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi.

3. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

4. Ikú wé mọ́ mi bí okùn,ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi rírú omi.

5. Isà òkú yí mi ká,tàkúté ikú sì dojú kọ mí.

6. Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA,Ọlọrun mi ni mo ké pè.Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀,ó sì tẹ́tí sí igbe mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 18