Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 17:8-12 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú,dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ;

9. lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí,àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

10. Ojú àánú wọn ti fọ́,ọ̀rọ̀ ìgbéraga sì ń ti ẹnu wọn jáde.

11. Wọn ń lépa mi; wọ́n sì ti yí mi ká báyìí;wọn ń ṣọ́ bí wọn ó ṣe bì mí ṣubú.

12. Wọ́n dàbí kinniun tí ó ṣetán láti pa ẹran jẹ,àní bí ọmọ kinniun tí ó ba ní ibùba.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 17