Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 144:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ,n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ.

10. Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là.

11. Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà,gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

12. Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa,jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà,kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé,tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba.

13. Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ,kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun,àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa.

14. Kí àwọn mààlúù wa lóyún,kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ;kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa.

15. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí;ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 144