Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 142:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo ké pe OLUWA,mo gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè sí i.

2. Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi palẹ̀ níwájú rẹ̀,mo sọ ìṣòro mi fún un.

3. Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì,ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà.Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún miní ọ̀nà tí mò ń rìn.

4. Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká,mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi;kò sí ààbò fún mi,ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi.

5. Mo ké pè ọ́, OLUWA,mo ní, “Ìwọ ni ààbò mi,ìwọ ni ìpín mi lórí ilẹ̀ alààyè.”

6. Gbọ́ igbe mi;nítorí wọ́n ti rẹ̀ mí sílẹ̀ patapata.Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi,nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

7. Yọ mí kúrò ninu ìhámọ́,kí n lè yin orúkọ rẹ lógo.Àwọn olódodo yóo yí mi ká,nítorí ọpọlọpọ oore tí o óo ṣe fún mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 142