Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 139:4-21 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata.

5. O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn;o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi.

6. Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi,ó ga jù, ojú mi kò tó o.

7. Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀?Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi?

8. Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀!Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀.

9. Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá,kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí,

10. níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ rẹ ni yóo máa tọ́ mi,tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo sì dì mí mú.

11. Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀,kí ọ̀sán di òru fún mi,

12. òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ;òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn.

13. Nítorí ìwọ ni o dá inú mi,ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi.

14. Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́;ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!O mọ̀ mí dájú.

15. Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀,tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí,kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ.

16. Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi,o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún misinu ìwé rẹ,kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.

17. Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi!Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye.

18. Bí mo bá ní kí n kà wọ́n,wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ;nígbà tí mo bá sì jí,ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà.

19. Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú,kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi.

20. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ nípa rẹ,àwọn ọ̀tá rẹ ń ba orúkọ rẹ jẹ́.

21. OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ;mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ?

Ka pipe ipin Orin Dafidi 139