Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 111:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ yin OLUWA!N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn,láàrin àwọn olódodo,ati ní àwùjọ àwọn eniyan.

2. Iṣẹ́ OLUWA tóbi,àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri.

3. Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo,òdodo rẹ̀ sì wà títí lae.

4. OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀.

5. A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀,a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae.

6. Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀,nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

7. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà,gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú.

8. Wọ́n wà títí lae ati laelae,ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin.

9. Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀,ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae,mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀.

10. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé.Títí lae ni ìyìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 111