Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 101:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo,OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí.

2. N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n;nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi?N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi.

3. N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi.Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun.N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan.

4. Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi,n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan,

5. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi,n óo pa á run,n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè.

6. N óo máa fi ojurere wo àwọn olóòótọ́ ní ilẹ̀ náà,kí wọ́n lè máa bá mi gbé;ẹni tí ó bá sì ń hu ìwà pípé ni yóo máa sìn mí.

7. Ẹlẹ́tàn kankan kò ní gbé inú ilé mi;bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kankan kò ní dúró níwájú mi.

8. Ojoojumọ ni n óo máa pa àwọn eniyan burúkú run ní ilẹ̀ náà,n óo lé gbogbo àwọn aṣebi kúrò ninu ìlú OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 101