Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 9:21-23 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Nígbà mìíràn, ìkùukùu náà lè má dúró lórí Àgọ́ Àjọ ju àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀ lọ, sibẹsibẹ, nígbàkúùgbà tí ìkùukùu bá kúrò lórí Àgọ́ Àjọ ni àwọn ọmọ Israẹli máa ń tẹ̀síwájú.

22. Kì báà sì jẹ́ ọjọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, níwọ̀n ìgbà tí ìkùukùu náà bá sì wà ní orí Àgọ́ Àjọ, wọn yóo dúró ni. Ṣugbọn bí ó bá ti gbéra ni àwọn náà yóo tẹ̀síwájú.

23. Nígbà tí OLUWA bá fún wọn láṣẹ ni wọ́n máa ń pàgọ́, nígbà tí ó bá sì tó fún wọn láṣẹ ni wọ́n tó máa ń gbéra.

Ka pipe ipin Nọmba 9