Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 8:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Aaroni gbé àwọn fìtílà náà ka orí ọ̀pá wọn, kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

4. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni wọ́n fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà, láti ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ títí dé ìtànná orí rẹ̀. Mose ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí OLUWA fi hàn án.

5. OLUWA sọ fún Mose pé,

6. “Ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.

7. Kí o wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, kí wọ́n fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì di mímọ́.

8. Kí wọ́n mú akọ mààlúù kékeré kan ati ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ wá. Kí wọ́n sì mú akọ mààlúù kékeré mìíràn wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

9. Lẹ́yìn náà, pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí àwọn ọmọ Lefi sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

10. Kó àwọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, kí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí,

11. kí Aaroni alufaa wá ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn OLÚWA.

Ka pipe ipin Nọmba 8