Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 8:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA rán Mose pé

2. kí ó sọ fún Aaroni pé, nígbà tí Aaroni bá tan fìtílà mejeeje, kí ó gbé wọn sórí ọ̀pá fìtílà kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju ọ̀pá náà.

3. Aaroni gbé àwọn fìtílà náà ka orí ọ̀pá wọn, kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

4. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni wọ́n fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà, láti ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ títí dé ìtànná orí rẹ̀. Mose ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí OLUWA fi hàn án.

5. OLUWA sọ fún Mose pé,

6. “Ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.

7. Kí o wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, kí wọ́n fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì di mímọ́.

Ka pipe ipin Nọmba 8