Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 7:69-86 BIBELI MIMỌ (BM)

69. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

70. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

71. Ahieseri ọmọ Amiṣadai, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia.

72. Ní ọjọ́ kọkanla ni Pagieli ọmọ Okirani, olórí àwọn ẹ̀yà Aṣeri mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

73. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ.

74. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari;

75. akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

76. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

77. Pagieli ọmọ Okirani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un kalẹ̀, pẹlu òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, fún ẹbọ alaafia.

78. Ní ọjọ́ kejila ni Ahira ọmọ Enani, olórí àwọn ẹ̀yà Nafutali, mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

79. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, pẹlu abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ.

80. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari;

81. akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

82. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

83. Ahira, ọmọ Enani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia.

84. Ní àpapọ̀, àwọn nǹkan ọrẹ tí àwọn olórí mú wá fún yíya pẹpẹ sí mímọ́ ní ọjọ́ tí a fi àmì òróró yà á sí mímọ́ ni: abọ́ fadaka mejila, àwo fadaka mejila, àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe mejila,

85. ìwọ̀n àwo fadaka kọ̀ọ̀kan jẹ́ aadoje (130) ṣekeli; ìwọ̀n gbogbo àwọn abọ́ fadaka náà jẹ́ ẹgbaa ṣekeli ó lé irinwo (2,400). Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n.

86. Ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àwo kòtò mejeejila tí wọ́n kún fún turari jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá mẹ́wàá. Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n. Ìwọ̀n àwọn àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe jẹ́ ọgọfa (120) ṣekeli.

Ka pipe ipin Nọmba 7