Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 7:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ tí Mose gbé Àgọ́ Àjọ dúró, tí ó sì ta òróró sí i tòun ti gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, ati pẹpẹ pẹlu gbogbo ohun èlò rẹ̀,

2. àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, tí wọ́n sì wà pẹlu Mose nígbà tí ó ka àwọn eniyan Israẹli,

3. mú ọrẹ ẹbọ wá siwaju OLUWA. Ọkọ̀ ẹrù mẹfa ati akọ mààlúù mejila. Ọkọ̀ ẹrù kọ̀ọ̀kan fún olórí meji meji, ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan fún olórí kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mú àwọn ẹbọ wọnyi wá sí ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́.

4. OLUWA sọ fún Mose pé

5. kí ó gba àwọn ẹbọ náà lọ́wọ́ wọn fún lílò ninu Àgọ́ Àjọ, kí ó sì pín wọn fún olukuluku àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn olukuluku wọn ti rí.

6. Mose bá gba àwọn ọkọ̀ ẹrù ati àwọn akọ mààlúù náà, ó kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi.

7. Ó fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ọkọ̀ ẹrù meji ati akọ mààlúù mẹrin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn.

8. Ó fún àwọn ọmọ Merari ní ọkọ̀ ẹrù mẹrin ati akọ mààlúù mẹjọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn, lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni alufaa.

9. Ṣugbọn àwọn ọmọ Kohati ni Mose kò fún ní nǹkankan, nítorí pé àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n máa ń fi èjìká rù ni iṣẹ́ ìsìn wọn jẹ mọ́.

10. Àwọn olórí náà rú ẹbọ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ ní ọjọ́ tí wọ́n ta òróró sí i, láti yà á sí mímọ́. Wọ́n mú ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ.

Ka pipe ipin Nọmba 7