Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 34:3-14 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn.

4. Yóo sì yí láti ìhà gúsù lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Akirabimu, yóo sì la aṣálẹ̀ Sini kọjá lọ títí dé ìhà gúsù Kadeṣi Banea ati títí dé Hasari Adari ati títí dé Asimoni.

5. Yóo sì yí láti Asimoni lọ dé odò Ijipti, òkun ni yóo sì jẹ́ òpin rẹ̀.

6. “Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Òkun ni yóo jẹ́ ààlà yín.

7. “Ní ìhà àríwá, ààlà yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ òkun ńlá lọ títí dé Òkè Hori.

8. Láti ibẹ̀ lọ dé ẹnu ibodè Hamati, títí dé Sedadi,

9. Sifironi ati Hasari Enani.

10. “Ààlà ìhà ìlà oòrùn yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ Hasari Enani lọ sí Ṣefamu.

11. Yóo lọ sí ìhà gúsù sí Ribila ní ìhà ìlà oòrùn Aini títí lọ sí àwọn òkè tí wọ́n wà létí ìhà ìlà oòrùn Òkun-Kinereti.

12. Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.”

13. Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ óo fi gègé pín. Ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an ààbọ̀ yòókù.

14. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ilẹ̀ tiwọn, tí a pín gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

Ka pipe ipin Nọmba 34