Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 3:21-32 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Geriṣoni ni baba ńlá àwọn ọmọ Libini ati àwọn ọmọ Ṣimei.

22. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn, láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó dín ẹẹdẹgbẹta (7,500).

23. Àwọn ọmọ Geriṣoni yóo pàgọ́ tiwọn sẹ́yìn Àgọ́ Àjọ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.

24. Eliasafu ọmọ Laeli ni yóo jẹ́ olórí wọn.

25. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati Àgọ́ Àjọ, aṣọ ìbòrí rẹ̀, ati aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀;

26. aṣọ tí wọ́n ń ta sí àgbàlá, aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọ àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, ati okùn, ati gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò pẹlu rẹ̀.

27. Kohati ni baba ńlá àwọn ọmọ Amramu ati àwọn ọmọ Iṣari, àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli.

28. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta (8,600). Àwọn ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́.

29. Àwọn ọmọ Kohati yóo pàgọ́ tiwọn sí ẹ̀gbẹ́ Àgọ́ Àjọ ní ìhà gúsù.

30. Elisafani ọmọ Usieli ni yóo jẹ́ olórí wọn.

31. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àpótí majẹmu ati tabili, ọ̀pá fìtílà ati àwọn pẹpẹ, ati àwọn ohun èlò ní ibi mímọ́, tí àwọn alufaa máa ń lò fún iṣẹ́ ìsìn; ati aṣọ ìbòjú, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ohun èlò wọnyi.

32. Eleasari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo máa ṣe alákòóso àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi, òun ni yóo sì máa ṣe àkóso àwọn tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́.

Ka pipe ipin Nọmba 3