Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 29:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.

7. “Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

8. Kí ẹ fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

9. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan;

10. ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan,

11. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo tún fi òbúkọ mìíràn rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ pẹlu.”

12. “Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò ní ṣe iṣẹ́ kankan fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún náà. Àjọ̀dún àyẹ́sí ni fún OLUWA.

13. Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹtala, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

14. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa, fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kọ̀ọ̀kan,

15. ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

16. pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

17. “Ní ọjọ́ keji, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mejila, àgbò meji, ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

Ka pipe ipin Nọmba 29