43. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé irinwo (64,400).
44. Àwọn ọmọ Aṣeri ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Imina, ìdílé Iṣifi ati ìdílé Beria.
45. Àwọn ọmọ Beria ni: ìdílé Heberi ati ìdílé Malikieli.
46. Orúkọ ọmọ Aṣeri obinrin sì ni Sera.
47. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400).
48. Àwọn ọmọ Nafutali ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Jahiseeli, ìdílé Guni,
49. ìdílé Jeseri ati ìdílé Ṣilemu.
50. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Nafutali jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé egbeje (45,400).
51. Gbogbo wọn ní àpapọ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (601,730).
52. OLUWA sọ fún Mose pé,
53. “Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn.
54. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn.