Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 24:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Balaamu tún sọ fún Balaki pé, “Èmi ń lọ sí ilé mi, ṣugbọn jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ọ nípa ohun tí àwọn eniyan wọnyi yóo ṣe sí àwọn eniyan rẹ ní ẹ̀yìn ọ̀la.”

15. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, pé,“Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí,ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú.

16. Ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun,tí ó ní ìmọ̀ ẹni tí ó ga jùlọ,tí ó sì ń rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare.Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ kò wà ní dídì.

17. Mo wo ọjọ́ iwájú rẹ,mo sì rí ẹ̀yìn ọ̀la rẹ.Ìràwọ̀ kan yóo jáde wá láàrin àwọn ọmọ Jakọbu,ọ̀pá àṣẹ yóo ti ààrin àwọn ọmọ Israẹli jáde wá;yóo run àwọn àgbààgbà Moabu,yóo sì wó àwọn ará Seti palẹ̀.

18. Yóo ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní Edomu,yóo sì gba ilẹ̀ wọn.Yóo ṣẹgun àwọn ará Seiri tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wọn,yóo sì gba ilẹ̀ wọn.Israẹli yóo sì máa pọ̀ sí i ní agbára.

19. Láti inú ìdílé Jakọbu ni àṣẹ ọba yóo ti jáde wá,yóo sì pa àwọn tí ó kù ninu ìlú náà run.”

20. Nígbà tí ó wo Amaleki, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé:“Amaleki ni orílẹ̀-èdè tí ó lágbára jùlọ,Ṣugbọn yóo ṣègbé níkẹyìn.”

21. Nígbà tí ó wo àwọn ará Keni, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé:“Ibi ìpamọ́ tí ẹ̀ ń gbédàbí ìtẹ́ tí ó wà lórí àpáta gíga.

22. Ṣugbọn ẹ̀yin ará Keni yóo di ẹni ìparun,àwọn ará Aṣuri yóo ko yín lẹ́rú.”

23. Balaamu tún fi òwe sọ ọ̀rọ̀ wọnyi:“Ta ni yóo là nígbà tí Ọlọrun bá ṣe nǹkan wọnyi?

24. Àwọn ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n kún fún ọmọ ogun yóo wá láti Kitimu,wọn yóo borí àwọn ará Aṣuri ati Eberi,ṣugbọn Kitimu pàápàá yóo ṣègbé.”

25. Balaamu bá dìde, ó pada sí ilé rẹ̀; Balaki náà bá pada sí ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọmba 24