Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 21:21-30 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Àwọn ọmọ Israẹli bá ranṣẹ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori pé,

22. “Jọ̀wọ́, gbà wá láàyè láti gba orí ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà wọ inú oko yín, tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi kànga yín. Ojú ọ̀nà ọba ni a óo máa rìn títí a óo fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”

23. Sihoni kò gbà kí àwọn ọmọ Israẹli gba orí ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Ṣugbọn ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Jahasi ninu aṣálẹ̀.

24. Àwọn ọmọ Israẹli pa pupọ ninu wọn, wọ́n gba ilẹ̀ wọn láti odò Arinoni lọ dé odò Jaboku títí dé ààlà àwọn ará Amoni. Wọn kò gba ilẹ̀ àwọn ará Amoni nítorí pé wọ́n jẹ́ alágbára.

25. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ìlú àwọn ará Amori, Heṣiboni ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, wọ́n sì ń gbé inú wọn.

26. Heṣiboni ni olú ìlú Sihoni, ọba àwọn ará Amori. Ọba yìí ni ó bá ọba Moabu jà, ó sì gba ilẹ̀ rẹ̀ títí dé odò Arinoni.

27. Ìdí èyí ni àwọn akọrin òwe ṣe ń kọrin pé:“Wá sí Heṣiboni!Jẹ́ kí á tẹ ìlú ńlá Sihoni dó,kí á sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

28. Ní àkókò kan, láti ìlú Heṣiboni,àwọn ọmọ ogun Sihoni jáde lọ bí iná;wọ́n run ìlú Ari ní Moabu,ati àwọn oluwa ibi gíga Arinoni.

29. Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé! Ẹ di ẹni ìparun, ẹ̀yin ọmọ oriṣa Kemoṣi!Ó ti sọ àwọn ọmọkunrin yín di ẹni tí ń sálọ fún ààbò;ó sì sọ àwọn ọmọbinrin yín di ìkógunfún Sihoni ọba àwọn ará Amori.

30. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti pa ìrandíran wọn run,láti Heṣiboni dé Diboni,láti Naṣimu dé Nofa lẹ́bàá Medeba.”

Ka pipe ipin Nọmba 21