Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 20:21-29 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Nígbà tí àwọn ará Edomu kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli gba ilẹ̀ wọn kọjá, wọ́n bá gba ọ̀nà ibòmíràn.

22. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Kadeṣi, wọ́n wá sí òkè Hori

23. ní agbègbè ilẹ̀ Edomu. Níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose ati Aaroni pé,

24. “Níhìn-ín ni Aaroni yóo kú sí, kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí pé n óo fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ̀yin mejeeji lòdì sí àṣẹ mi ní Meriba.

25. Nítorí náà mú Aaroni ati ọmọ rẹ̀ Eleasari wá sórí òkè Hori.

26. Níbẹ̀ ni kí o ti bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, kí o gbé e wọ Eleasari. Níbẹ̀ ni Aaroni óo kú sí.”

27. Mose ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, gbogbo wọn sì gòkè Hori lọ níwájú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

28. Mose bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, ó gbé e wọ Eleasari. Aaroni sì kú sí orí òkè náà, Mose ati Eleasari sì sọ̀kalẹ̀.

29. Nígbà tí àwọn eniyan náà mọ̀ pé Aaroni ti kú, wọ́n ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́.

Ka pipe ipin Nọmba 20