Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 20:14-26 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Mose rán oníṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu pé, “Arakunrin rẹ ni àwa ọmọ Israẹli jẹ́, o sì mọ gbogbo àwọn ìṣòro tí ó ti dé bá wa.

15. Bí àwọn baba ńlá wa ṣe lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ará Ijipti lo àwọn baba ńlá wa ati àwa náà ní ìlò ẹrú.

16. Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ.

17. Jọ̀wọ́ gbà wá láàyè kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu oko yín tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi inú kànga yín. Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, a kò ní yà sí ọ̀tún tabi òsì títí tí a óo fi kọjá ilẹ̀ rẹ.”

18. Ṣugbọn àwọn ará Edomu dáhùn pé, “A kò ní jẹ́ kí ẹ gba ilẹ̀ wa kọjá, bí ẹ bá sì fẹ́ kọjá pẹlu agídí, a óo ba yín jagun.”

19. Àwọn ọmọ Israẹli ní, “Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, bí àwa tabi ẹran wa bá tilẹ̀ mu omi yín, a óo sanwó rẹ̀. Ohun kan tí a sá fẹ́ ni pé kí ẹ jẹ́ kí á kọjá.”

20. Àwọn ará Edomu tún dáhùn pé, “Rárá o, ẹ kò lè kọjá.” Wọ́n sì jáde pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun ati agbára ogun láti lọ dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Israẹli.

21. Nígbà tí àwọn ará Edomu kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli gba ilẹ̀ wọn kọjá, wọ́n bá gba ọ̀nà ibòmíràn.

22. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Kadeṣi, wọ́n wá sí òkè Hori

23. ní agbègbè ilẹ̀ Edomu. Níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose ati Aaroni pé,

24. “Níhìn-ín ni Aaroni yóo kú sí, kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí pé n óo fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ̀yin mejeeji lòdì sí àṣẹ mi ní Meriba.

25. Nítorí náà mú Aaroni ati ọmọ rẹ̀ Eleasari wá sórí òkè Hori.

26. Níbẹ̀ ni kí o ti bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, kí o gbé e wọ Eleasari. Níbẹ̀ ni Aaroni óo kú sí.”

Ka pipe ipin Nọmba 20