Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 2:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ní ìhà gúsù ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí wọn.

11. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500).

12. Ẹ̀yà Simeoni ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Reubẹni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni yóo jẹ́ olórí wọn.

13. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mọkandinlọgbọn ó lé eedegbeje (59,300).

14. Ẹ̀yà Gadi ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Simeoni; Eliasafu ọmọ Reueli ni yóo jẹ́ olórí wọn.

15. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650).

16. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Reubẹni jẹ́ ẹgbaa marundinlọgọrin ó lé aadọta lé ní egbeje (151,450). Àwọn ni yóo máa tẹ̀lé ibùdó Juda nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn.

17. Lẹ́yìn náà, Àgọ́ Ẹ̀rí yóo ṣí, pẹlu àgọ́ àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n ti pàgọ́ yí Àgọ́ náà ká, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa ṣí, olukuluku ní ipò rẹ̀, pẹlu àsíá ẹ̀yà rẹ̀.

18. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Efuraimu yóo máa wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọrí; Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí wọn.

19. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).

20. Ẹ̀yà Manase ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli, ọmọ Pedasuri, ni yóo sì jẹ́ olórí wọn.

21. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaafa ó lé igba (32,200).

Ka pipe ipin Nọmba 2