Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 18:23-32 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìlànà ayérayé ni èyí fún arọmọdọmọ yín, wọn kò tún gbọdọ̀ ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli;

24. nítorí pé gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún mi ni mo ti fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìní. Ìdí sì nìyí tí mo fi sọ fun wọn pé wọn kò lè ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli.”

25. OLUWA rán Mose:

26. kí ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi pé, “Nígbà tí ẹ bá gba ìdámẹ́wàá tí OLUWA ti fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ óo san ìdámẹ́wàá ninu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA.

27. Ọrẹ yìí yóo dàbí ọrẹ ọkà titun, ati ọtí waini titun, tí àwọn àgbẹ̀ ń mú wá fún OLUWA.

28. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ọrẹ yín wá fún OLUWA ninu ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá san fun yín. Ẹ óo mú ọrẹ tí ó jẹ́ ti OLUWA wá fún Aaroni alufaa.

29. Ninu èyí tí ó dára jù ninu àwọn ohun tí ẹ bá gbà ni kí ẹ ti san ìdámẹ́wàá yín.

30. Nígbà tí ẹ bá ti san ìdámẹ́wàá yín lára èyí tí ó dára jù, ìyókù jẹ́ tiyín, gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ ṣe máa ń kórè oko rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti san ìdámẹ́wàá rẹ̀.

31. Ẹ̀yin ati ẹbí yín lè jẹ ìyókù níbikíbi tí ẹ bá fẹ́, nítorí pé ó jẹ́ èrè yín fún iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe ninu Àgọ́ Àjọ.

32. Ẹ kò ní jẹ̀bi nígbà tí ẹ bá jẹ ẹ́, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti san ìdámẹ́wàá ninu èyí tí ó dára jù. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà sọ ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli di àìmọ́ nípa jíjẹ wọ́n láìsan ìdámẹ́wàá wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ óo kú.”

Ka pipe ipin Nọmba 18