Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 16:37-46 BIBELI MIMỌ (BM)

37. “Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni, alufaa pé kí ó kó àwọn àwo turari wọ̀n-ọn-nì kúrò láàrin àjókù àwọn eniyan náà. Kí ó sì da iná inú wọn káàkiri jìnnà jìnnà nítorí àwọn àwo turari náà jẹ́ mímọ́.

38. Kí ó mú àwo turari àwọn ọkunrin tí wọ́n kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ, nítorí níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti mú wọn wá siwaju OLUWA, wọ́n ti di mímọ́. Èyí yóo sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.”

39. Eleasari bá kó àwọn àwo turari náà tí àwọn tí ó jóná fi rú ẹbọ, ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ.

40. Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari.

41. Ní ọjọ́ keji gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ẹ pa àwọn eniyan OLUWA.”

42. Ó sì ṣe nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni, wọn bojúwo ìhà Àgọ́ Àjọ, wọ́n sì rí i tí ìkùukùu bò ó, ògo OLUWA sì farahàn.

43. Mose ati Aaroni lọ dúró níwájú Àgọ́ Àjọ,

44. OLUWA sì sọ fún Mose pé,

45. “Kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi kí n lè pa wọ́n run ní ìṣẹ́jú kan.”Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀.

46. Mose sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo turari rẹ, fi ẹ̀yinná sinu rẹ̀ láti orí pẹpẹ kí o sì fi turari sí i. Ṣe kíá, lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan náà láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí ibinu OLUWA ti ru, àjàkálẹ̀ àrùn sì ti bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.”

Ka pipe ipin Nọmba 16