Mose sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo turari rẹ, fi ẹ̀yinná sinu rẹ̀ láti orí pẹpẹ kí o sì fi turari sí i. Ṣe kíá, lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan náà láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí ibinu OLUWA ti ru, àjàkálẹ̀ àrùn sì ti bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.”